Connect with us

News

IPÒ GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́ YẸ́ KÓ MA YÍ KÁÀKIRI Ẹ̀KÙNJẸKÙN – OLÙṢỌ́-ÀGÙNTÀN FAVOUR ADÉWÁLÉ ADÉWỌYIN

Published

on

Olùṣọ́-Àgùntàn Favour Adéwálé Adéwọyin, akọ̀wé gbogbogbo Ẹgbẹ́ Àjọṣepọ̀ Fún Ìtẹ̀síwájú Gbogbo Wa, ti kéde pé ó ṣe pàtàkì kí ipò Gómìnà yí káàkiri gbogbo ìpínlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àwọn ìpínlẹ̀ mìíràn. Ó sọ pé bí ìjọba bá yí ka gbogbo agbègbè, àjọṣe àti ìdàgbàsókè yóò túbọ̀ gbilẹ̀.

Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tó ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ̀ pàtàkì lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ti wà ní ìfọ̀kànbalẹ̀ pẹ̀lú ìdáhùn lórí ìtẹ̀síwájú òṣèlú rẹ̀. Lát’ígbà tí wọ́n yà ìpínlẹ̀ yí kúrò l’ọwọ́ ìpínlẹ̀ Ọṣun ní ọdún 1991 ní ìjọba Ológun Ọ̀gágun Ibrahim Badamosi Babangida, ipò Gómìnà ti di nkan tó ṣàjèjì níbi tó ti yẹ kó má yí káàkiri.

Nígbà kan rí, ìjọba ìbílẹ̀ Ìbàdàn ti ṣe àṣà láti gbà ipò Gómìnà lọ́wọ́. Yàtọ̀ sí àkókò náà, àwọn àgbègbè míràn bíi Òkèògùn, Ọ̀yọ́, Ìbàràpá, àti Ògbómọ̀ṣọ́ ti kò tíì rí ànfàní láti mú ipò Gómìnà. Olùṣọ́-Àgùntàn Favour Adéwálé Adéwọyin sọ pé ó yẹ kí ipò yí yí káàkiri, kí gbogbo ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ le ni ànfàní láti ṣàkóso.

Ní ọdún 1979 sí 1983, Olóyè Bọ́lá Ìgè, tó jẹ́ ọmọ bíbí Ẹ̀sà-Òkè ní ìpínlẹ̀ Ọṣun báyìí, ni Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Gbólóhùn kan tó sọ nígbà yẹn pé “Kò sí ọmọ Ìbàdàn tó le jẹ Gómìnà” ti yípa òṣèlú ìpínlẹ̀ yí títí di òní.

Lẹ́yìn Ìjọba Olóyè Bọ́lá Ìgè, Ọ̀mọwé Victor Ọmọlolú Olúnlọ́yọ̀ ṣe Gómìnà láti ìpínlẹ̀ Ìbàdàn, ṣùgbọ́n òṣèlú kókó ló mú kí kókó yí pa àṣà rẹ̀. Nígbà tí Ìjọba Ológun gba àṣẹ ní 1983, wọ́n yọ gbogbo àwọn alágbádá, tí wọ́n sì fi Ọ̀gágun Mohammadu Buhari àti Ọ̀gágun Túndé Ìdíàgbọn ṣèjọba.

Látọdún 1999, tí ìjọba ti wá padà s’ọwọ́ àwọn alágbádá, ipò Gómìnà kò ti yí káàkiri gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ. Púpọ̀ nínú àwọn tó di Gómìnà ni wọ́n ti wá láti ìlú Ìbàdàn, nígbà tí Òkèògùn, Ọ̀yọ́, Ìbàràpá, àti Ògbómọ̀ṣọ́ ti kò tíì ní ànfàní tó peye.

Ẹgbẹ́ “Àjọṣepọ̀ Fún Ìtẹ̀síwájú Gbogbo Wa” ti gbé Ìgbẹ́sẹ̀ kan dide láti gbìyànjú kí àwọn àgbègbè yókù ní ànfàní láti fi aṣojú wọn jọba gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe é ní àwọn ìpínlẹ̀ míràn.

Olùṣọ́-Àgùntàn Favour Adéwálé Adéwọyin pẹ̀lú ẹgbẹ́ rẹ̀ ti gbà pé “Màkàn màkàn l’oyè é kán, oyè tó kan ará Awó ń bọ̀ wá kan ará Ẹdẹ.” Wọ́n gbà pé àjọṣepọ̀ àti ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní kókó, kódà bí wọ́n ṣe ń ṣe é ní àwọn ìpínlẹ̀ míràn ní ìwọ̀ òòrun Gúúsù.

A dúpẹ́ l’ọwọ́ Ọlọ́run, a sì ń gbàdúrà pé ìtẹ̀síwájú òṣèlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yíò fi ìdàgbàsókè bọ̀ wá.

Ẹ ṢÁNÚ, Ẹ TU ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́ SÍLẸ̀!

Click to comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Trending