News
ÌPALÁRA YORÙBÁ: Ọ̀JỌ̀ ÀGBÉYẸ̀WÒ TÓ FÚN Ẹ̀SÌN, ÀṢÀ, ÀTẸ̀DÈ WA LÓUNJÚ—BABÁJÍDÉ Ọ̀JẸ́DÌRÁN DÁRÍ JÌJÍRÒRÒ LÓRÍ ÌJÀǸBÁ ÀṢÀ NÍ ÌBÀRÀPÁ
Níbi àkànṣe ìpàdé àfihàn àṣà tí arábìnrin Bọ́lá Olúbím̄pé Akíntẹ́yẹ ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ ní Ìbàràpá, olóyè Babájídé Ọ̀jẹ́dìrán, Olórí Àṣà Ilé Àdúláwọ̀, B.A. Yorùbá láti Yunifásítì Ìlɔrin, ṣàfihàn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àkórí “Ìpalára Yorùbá,” nínú èyí tó dá lórí bí àṣà, èdè, àti lítíréṣọ̀ Yorùbá ṣe ń ṣakàtá ní àwùjọ wa lónìí. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ àkànṣe ìpẹ̀yà sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn olùkànsí láti gbà àṣà wa là padà, kí a lè dènà ìparun ẹ̀rí wa gẹ́gẹ́ bí ọmọ Yorùbá. Ní kíkún, ẹ̀yin ni gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ ó:
Ka gbogbo ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà
ÌPALÁRA YORÙBÁ…..Babajide Ojediran*
ÈYÍ NI ÌDÁNILẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ ṢÓKÍ LÓRÍ ORÍ Ọ̀RỌ̀ TÓ SỌ PÉ ÌPALÁRA YORÙBÁ NÍBI ÀKÀNṢE ÈTÒ ÀFIHÀN ÀṢÀ NÍ ÌBÀRÀPÁ TÍ ARÁBÌNRIN BỌLÁ OLÚBÍMPÉ AKÍNTẸ́YẸ ṢE ÀGBÉKALẸ̀ RẸ̀. LÁTI ỌWỌ́ BABÁJÍDÉ Ọ̀JẸ́DÌRAN.
Ṣáájú ohun gbogbo, ìkínni mi lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run Elédùmarè tó dá ohun gbogbo, tó sì jẹ́ kí ọjọ́ òní ṣeéṣe. Mo kí gbogbo orí adé àti ọrùn ìlẹ̀kẹ̀, mo kí bọ̀rọ̀kìnní, ọ̀tọ̀kùlú, ọlọ́lá, gbogbo ẹ̀yin tí a fi ìwé pè. Mo kí Arábìnrin Bọ́lá Olúbím̄pé Akíntẹ́yẹ fún ìran ètò yìí àti àgbékalẹ̀ rẹ̀. Èyí kò ní jẹ́ àṣemọ.
Bákan náà, mo kí ìsun, mo sì kí ìwàrẹ̀, mo kí ọmọdé, mo sì kí àgbà. Tí a bá gún iyán, tí a se ọbẹ̀, tí a kò bá rẹ́ni je, a jẹ́ pé a fi ṣègbé ni. Mo kí gbogbo ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́, pàtàkì jùlọ ẹ̀yin oloyè àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyìí àti ẹ̀yìn ajìjà-ǹ-gbara. Elédùà kò ní jẹ́ kí wọ́n fi òkú yín ránṣẹ́ sílé o. (Àmín àṣẹ). Ṣùgbọ́n tí a bá ń sukún, a máa ń ríran. Kí páńsá yín fura o, kó má baà já síná.
Lẹ́yìn tí mo ti júbà tán, ẹ jẹ́ kónìí yẹ mi o. Mo ti kágò, n ò gbọdọ̀ dẹ̀ran àmúso o.
Ní ṣókí, ìdánilẹkọ̀ọ́ yìí yóò dá lé
1) Kí ni Yorùbá?
2) Mẹ́talọ́kan Yorùbá
3) Àgbéyẹ̀wò Àgbékalẹ̀ Bọ́láńlé Bándélé
4) Ìpalára Tó Dé Bá Yorùbá
1) Kí ni Yorùbá?
Ní ìbèrẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dálẹ̀ Yorùbá, kò sí ọ̀rọ̀ tí ó ń jẹ Yorùbá sùgbọ́n ní ọdún 1900 ni a ṣe ìkójáde rẹ̀ bí ọmọ titun jòjòló. Ẹ̀yà Yorùbá kọ̀ọ̀kan ń jẹ́ orúkọ tirẹ̀ ni. Ọ̀yọ́ ń jẹ́ Ọ̀yọ́, Ifẹ̀ ń jẹ́ If abbl.
Ọ̀rọ̀ Yorùbá jáde gẹ́gẹ́ bíi èrò àwọ́n onímọ̀ kan pé láti ara àṣà àti ìgbàgbọ́ Yorùbá nínú ẹbọ rírú. Ló jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà súyọ láti ara “Yóò Rú’Bọ” ló dì Yorùbá. Àwọ̀n onimale míìràn ní láti ara orúkọ baba aláwo Odùduwà tí Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ “Yar’ Abba” ló dì Yorùbá. Abbl.
Ohun tó dájú ni wí pé, ọrọ Yorùbá yìí kó sì nínú ìṣẹ̀dálẹ̀ ìran àti ẹ̀yà Yorùbá.
2) Mẹ́talọ́kan Yorùbá
Ohun tí Yorùbá ń jẹ́ tàbí ohun Yorùbá ní ṣe pẹ̀lú jẹ́ mẹ́ta. A kò sì lè ya àwọn mẹ́tẹ̀tà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.
i) ÈDÈ
ii) ÀṢÀ
iii) LÍTÍRÉṢỌ̀.
Èyí tí ó je ẹ̀tanú ibẹ̀ ni èrò àwọn Òyìnbó pé Yorùbá kò ní LÍTÍRÉṢỌ̀ ti wọ́n. Òtítọ́ ni pé ọ̀rọ̀ tí à ń pè ní Lítíréṣọ̀ lè má jé ọ̀rọ̀ Yorùbá Ṣùgbọ́n gbogbo ẹ̀ya Lítíréṣọ̀ yìí ló pé sínú àṣà àti ìṣe Yorùbá. B.A. Iyá tí ọmọ rẹ̀ ń ké tí ó sì gbé ọmọ náà pọ̀n sẹ́yìn, tí ó wá ń pasẹ̀ fún ùn títí tó fí sùn. Látàrí pipasẹ̀ fún ọmọ ni eré – Oníṣe ti wáyé, àti ewì.
Àlọ́ ìjàpá ọkọ yẹ́nníbo, Ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ìtàn akọni ló bẹ̀rẹ̀ Ìtàn àròsọ. Egúngún aláré àti Ọdún ìbílẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ eré oníṣe. Ọ̀rọ̀ ìfitu òrìṣa lójú, orin ìdárayá lẹ́nu iṣẹ́ àti orin ìdárò ló bé Ewì ní ilẹ̀ Yorùbá.
3) Àgbéyẹ̀wò Àgbékalẹ̀ Bọ́láńlé Bándélé
Bọ́láńlé Bándélé jẹ́ ónimọ̀ tí ó ṣe àgbékalẹ̀ àròjínlẹ̀ ìbí Yorùbá gbé dúró lónìí. Ẹ jẹ́ kí á jọ fòye gbe.
i) Y
Eléyìí dúró fún Yorùbá pé nígbà kan ẹ̀wẹ̀, Yorùbá nìkan ni ó wà ní ilẹ̀ Káàárọ̀-o-ò-jíire.
ii) Y e
Eléyìí túmọ̀ sí pé àsìkò kan dé tí a bí àṣà àti Gẹ̀ẹ́sì sí àárin wa bíi ọmọ tuntun jòjòló. Àsìkò yìí, ẹni tí yóò fọ Gẹ̀ẹ́sì lẹ́nu ni ojú má ń tì. Wọn a máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ ni.
iii) Y E
Nígbà tó yá, Gẹ̀ẹ́sì náà ń dúró tá kànǹgbẹ̀n pẹ̀lú Yorùbá. Gẹ́ẹ̀sì náà àti àṣà rẹ̀ ti wá ń figa gbága pẹ̀lú Yorùbá. Àyè tí wá gba Gẹ̀ẹ́sì dáadáa.
iv) Ibi àwùjọ wa gbé dúró rèé. Gẹ̀ẹ́sì ti tẹrí Yorùbá ba. Ojú ti ń ti àwọn asọYorùbá níwájú àwọn asọGẹ̀ẹ́sì. A ti ń dawọ́ bo Yorùbá ní sísọ. A kò gbọ́ òwe mọ́. A kò sì fi èdè àti àṣà Yorùbá kọ́mọ́ mọ́. Gbogbo èèyàn ló fẹ́ sọ Gẹ̀ẹ́sí báyìí torí ẹni tó gbọ́ Yorùbá tí kò gbọ́ Gẹ̀ẹ́sì, bíi pé kò ráyé wá ni. Àwọ́n fẹ̀yìn jọ akọ̀wé ti wá pọ̀.
v) E
Ọjọ́ ń bọ̀ tí a kò ní gbúròó Yorùbá ní àwùjọ wa. Gẹ̀ẹ́sì nìkan ni á ṣẹ́kùn. Àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun ni á wá máa kọ́ wá ní Yorùbá.
4) Ìpalára Tó Dé Bá Yorùbá
Yorùbá ní òrìṣà tí a kò bá fi han ọmọ, kíkú ni irú òrìṣà bẹ́ẹ̀ máa ń kú. Bí Yorùbá ṣe dà lónìí, àlọ́wọ́sí gbogbo wà ní. Ìpalára Ti dé bá èdè àti àṣa wa. Èdè Yorùbá ti wá ń rùn lẹ́nu àwa ọmọ Yorùbá, àṣà wa kò wù ojú rí mọ́.
Èdè sì ni ọ̀pá kùtẹ̀lẹ̀ àṣà, tí èdè bá kú àṣà náà á kú. Ṣé bí a ó ṣe wá lajú lẹ̀ rèé tí Èdè àti àṣà Yorùbá yóò ròkun ìgbàgbé.
Èdè Yorùbá, àṣà Yorùbá kò ní tọwọ́ mi rèwàlẹ̀ àsà.
*Oloye Babajide Ojediran*
Olori Asa Ile Adulawo
B.A. Yorùbá, UNIVERSITY of Ilorin, Ilorin Nigeria
-
News3 years ago
FASU CRISIS: REDEMPTION FORUM CALL FOR PEACE, WRITES TEAM FOCUS
-
News2 years ago
BREAKING: PANIC IN IGBOORA AS SEGO BURNT TO ASHES … Towobowo market distrupted as motorcycle rate collector killed a minor.
-
News3 years ago
PANIC IN IGBOORA AS A PROMISING BATTERY CHARGER STABBED TO DEATH BY BROTHERS
-
Business3 years ago
ASAKO REPORTERS SET TO HONOUR ADEGOKE, ADEDIGBA, AKINLABI, OLUGBILE, OLANIPEKUN, OLARINDE,OWOTUTU, LATE OLU OF IGBOORA AND ONIPAKO
-
Events4 years ago
EXACTLY A YEAR AFTER, IGBOORA STUDENTS UNION FORMER PRESIDENT THANK SUPPORTERS
-
Business3 years ago
DOCTORAL DEGREE: OYSCATECH MANAGEMENT, FORMER MANAGEMENT, ISEYIN CAMPUS OF LAUTECH ACTING PROVOST, OTHERS HONOUR AGBOGUN
-
Business3 years ago
DELIBERATE PUBLICATION OF FAKE NEWS BY HASSAN OLAONIYE, PUBLISHER OF PEOPLESCONSCIENCE IS AN ABERRATION IN JOURNALISM PRACTICE
-
Business3 years ago
HON MURAINA AJIBOLA SAUBANA AND HIS NUMEROUS BILLS ON TERTIARY INSTITUTIONS: THE AYETE EXPERIENCE – KABIR O. AYINLA